Nigbana li o ṣí wọn ni iyè, ki iwe-mimọ́ ki o le yé wọn, O si wi fun wọn pe, Bẹ̃li a ti kọwe rẹ̀, pe, ki Kristi ki o jìya, ati ki o si jinde ni ijọ kẹta kuro ninu okú: Ati ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹ̀ṣẹ li orukọ rẹ̀, li orilẹ-ède gbogbo, bẹ̀rẹ lati Jerusalemu lọ. Ẹnyin si ni ẹlẹri nkan wọnyi. Si kiyesi i, Mo rán ileri Baba mi si nyin: ṣugbọn ẹ joko ni ilu Jerusalemu, titi a o fi fi agbara wọ̀ nyin, lati oke ọrun wá. O si mu wọn jade lọ titi nwọn fẹrẹ̀ de Betani, nigbati o si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o sure fun wọn. O si ṣe, bi o ti nsure fun wọn, a yà a kuro lọdọ wọn, a si gbé e lọ si ọrun. Nwọn si foribalẹ̀ fun u, nwọn si pada lọ si Jerusalemu pẹlu ayọ̀ pipọ: Nwọn si wà ni tẹmpili nigbagbogbo, nwọn mbu iyin, nwọn si nfi ibukun fun Ọlọrun. Amin.
Kà Luk 24
Feti si Luk 24
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 24:45-53
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò