Luk 24:44-48

Luk 24:44-48 YBCV

O si wi fun wọn pe, Nwọnyi li ọrọ ti mo sọ fun nyin, nigbati emi ti wà pẹlu nyin pe, A kò le ṣe alaimu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ ninu ofin Mose, ati ninu iwe awọn woli, ati ninu Psalmu, nipasẹ̀ mi. Nigbana li o ṣí wọn ni iyè, ki iwe-mimọ́ ki o le yé wọn, O si wi fun wọn pe, Bẹ̃li a ti kọwe rẹ̀, pe, ki Kristi ki o jìya, ati ki o si jinde ni ijọ kẹta kuro ninu okú: Ati ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹ̀ṣẹ li orukọ rẹ̀, li orilẹ-ède gbogbo, bẹ̀rẹ lati Jerusalemu lọ. Ẹnyin si ni ẹlẹri nkan wọnyi.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ