Luk 24:28-35

Luk 24:28-35 YBCV

Nwọn si sunmọ iletò ti nwọn nlọ: o si ṣe bi ẹnipe yio lọ si iwaju. Nwọn si rọ̀ ọ, wipe, Ba wa duro: nitori o di ọjọ alẹ, ọjọ si kọja tan. O si wọle lọ, o ba wọn duro. O si ṣe, bi o ti ba wọn joko tì onjẹ, o mu àkara, o sure si i, o si bù u, o si fifun wọn. Oju wọn si là, nwọn si mọ̀ ọ; o si nù mọ wọn li oju. Nwọn si ba ara wọn sọ pe, Ọkàn wa kò ha gbiná ninu wa, nigbati o mba wa sọ̀rọ li ọna, ati nigbati o ntumọ̀ iwe-mimọ́ fun wa? Nwọn si dide ni wakati kanna, nwọn pada lọ si Jerusalemu, nwọn si ba awọn mọkanla pejọ, ati awọn ti mbẹ lọdọ wọn, Nwipe, Oluwa jinde nitõtọ, o si ti fi ara hàn fun Simoni. Nwọn si ròhin nkan ti o ṣe li ọ̀na, ati bi o ti di mimọ̀ fun wọn ni bibu àkara.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ