Si kiyesi i, awọn meji ninu wọn nlọ ni ijọ na si iletò kan ti a npè ni Emmausi, ti o jina si Jerusalemu niwọn ọgọta furlongi. Nwọn mba ara wọn sọ̀rọ gbogbo nkan wọnyi ti o ṣẹlẹ̀. O si ṣe, nigbati nwọn mba ara wọn sọ, ti nwọn si mba ara wọn jirorò, Jesu tikararẹ̀ sunmọ wọn, o si mba wọn rìn lọ. Ṣugbọn a rú wọn li oju ki nwọn ki o máṣe le mọ̀ ọ. O si bi wọn pe, Ọ̀rọ kili ẹnyin mba ara nyin sọ, bi ẹnyin ti nrìn? Nwọn si duro jẹ, nwọn fajuro. Ọkan ninu wọn, ti a npè ni Kleopa, si dahùn wi fun u pe, Alejò ṣá ni iwọ ni Jerusalemu, ti iwọ kò si mọ̀ ohun ti o ṣe nibẹ̀ li ọjọ wọnyi? O si bi wọn pe, Kini? Nwọn si wi fun u pe, Niti Jesu ti Nasareti, ẹniti iṣe woli, ti o pọ̀ ni iṣẹ ati li ọ̀rọ niwaju Ọlọrun ati gbogbo enia: Ati bi awọn olori alufa ati awọn alàgba wa ti fi i le wọn lọwọ lati da a lẹbi iku, ati bi nwọn ti kàn a mọ agbelebu. Bẹ̃ni on li awa ti ni ireti pe, on ni iba da Israeli ni ìde. Ati pẹlu gbogbo nkan wọnyi, oni li o di ijọ kẹta ti nkan wọnyi ti ṣẹ.
Kà Luk 24
Feti si Luk 24
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 24:13-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò