Luk 23:27-31

Luk 23:27-31 YBCV

Ijọ enia pipọ li o ntọ̀ ọ lẹhin, ati awọn obinrin, ti npohùnrere ẹkún, ti nwọn si nṣe idarò rẹ̀. Ṣugbọn Jesu yiju pada si wọn, o si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ẹ má sọkun fun mi, ṣugbọn ẹ sọkun fun ara nyin, ati fun awọn ọmọ nyin. Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ̀ li eyiti ẹnyin o wipe, Ibukun ni fun àgan, ati fun inu ti kò bímọ ri, ati fun ọmú ti kò funni mu ri. Nigbana ni nwọn o bẹ̀rẹ si iwi fun awọn òke nla pe, Wó lù wa; ati fun awọn òke kekeke pe, Bò wa mọlẹ. Nitori bi nwọn ba nṣe nkan wọnyi sara igi tutù, kili a o ṣe sara gbigbẹ?

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ