Luk 23:26-34

Luk 23:26-34 YBCV

Bi nwọn si ti nfà a lọ, nwọn mu ọkunrin kan, Simoni ara Kirene, ti o nti igberiko bọ̀, on ni nwọn si gbé agbelebu na le, ki o mã rù u bọ̀ tẹle Jesu. Ijọ enia pipọ li o ntọ̀ ọ lẹhin, ati awọn obinrin, ti npohùnrere ẹkún, ti nwọn si nṣe idarò rẹ̀. Ṣugbọn Jesu yiju pada si wọn, o si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ẹ má sọkun fun mi, ṣugbọn ẹ sọkun fun ara nyin, ati fun awọn ọmọ nyin. Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ̀ li eyiti ẹnyin o wipe, Ibukun ni fun àgan, ati fun inu ti kò bímọ ri, ati fun ọmú ti kò funni mu ri. Nigbana ni nwọn o bẹ̀rẹ si iwi fun awọn òke nla pe, Wó lù wa; ati fun awọn òke kekeke pe, Bò wa mọlẹ. Nitori bi nwọn ba nṣe nkan wọnyi sara igi tutù, kili a o ṣe sara gbigbẹ? Nwọn si fà awọn meji lọ pẹlu, awọn arufin, lati pa pẹlu rẹ̀. Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Agbari, nibẹ̀ ni nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn arufin na, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ọkan li ọwọ́ òsi. Jesu si wipe, Baba, darijì wọn; nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe. Nwọn si pín aṣọ rẹ̀ lãrin ara wọn, nwọn di ìbo rẹ̀.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ