Luk 22:39-46

Luk 22:39-46 YBCV

Ó si jade, o si lọ bi iṣe rẹ̀ si òke Olifi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin. Nigbati o wà nibẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ sinu idẹwò. O si fi wọn silẹ niwọn isọko kan, o si kunlẹ o si ngbadura, Wipe, Baba, bi iwọ ba fẹ, gbà ago yi lọwọ mi: ṣugbọn ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe. Angẹli kan si yọ si i lati ọrun wá, o ngbà a ni iyanju. Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ. Nigbati o si dide kuro ni ibi adura, ti o si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o ba wọn, nwọn nsùn fun ibanujẹ, O si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nsùn si? ẹ dide, ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ́ sinu idẹwò.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ