Luk 22:31-38

Luk 22:31-38 YBCV

Oluwa si wipe, Simoni, Simoni, sawõ, Satani fẹ lati ni ọ, ki o le kù ọ bi alikama: Ṣugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ́ rẹ ki o má yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si yipada, mu awọn arakunrin rẹ li ọkàn le. O si wi fun u pe, Oluwa, mo mura tan lati bá ọ lọ sinu tubu, ati si ikú. O si wipe, Mo wi fun ọ, Peteru, akukọ ki yio kọ loni ti iwọ o fi sẹ́ mi li ẹrinmẹta pe, iwọ kò mọ̀ mi. O si wi fun wọn pe, Nigbati mo rán nyin lọ laini asuwọn, ati àpo, ati bàta, ọdá ohun kan da nyin bi? Nwọn si wipe, Rara o. Nigbana li o wi fun wọn pe, Ṣugbọn nisisiyi, ẹniti o ba li asuwọn, ki o mu u, ati àpo pẹlu: ẹniti kò ba si ni idà, ki o tà aṣọ rẹ̀, ki o si fi rà kan. Nitori mo wi fun nyin pe, Eyi ti a ti kọwe rẹ̀ kò le ṣe ki o má ṣẹ lara mi, A si kà a mọ awọn arufin. Nitori ohun wọnni nipa ti emi o li opin. Nwọn si wipe, Oluwa, sawõ, idà meji mbẹ nihinyi. O si wi fun wọn pe, O to.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ