Nigbati akokò si to, o joko ati awọn aposteli pẹlu rẹ̀.
O si wi fun wọn pe, Tinu-tinu li emi fẹ fi ba nyin jẹ irekọja yi, ki emi ki o to jìya:
Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio jẹ ninu rẹ̀ mọ́, titi a o fi mú u ṣẹ ni ijọba Ọlọrun.
O si gbà ago, nigbati o si ti dupẹ, o wipe, Gbà eyi, ki ẹ si pín i larin ara nyin.
Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi ijọba Ọlọrun yio fi de.
O si mú akara, nigbati o si ti dupẹ o bu u, o si fifun wọn, o wipe, Eyi li ara mi ti a fifun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi.
Bẹ̃ gẹgẹ lẹhin onjẹ alẹ, o si mu ago, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun li ẹ̀jẹ mi, ti a ta silẹ fun nyin.
Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ọwọ́ ẹniti o fi mi hàn wà pẹlu mi lori tabili.
Ọmọ-enia nlọ nitõtọ bi a ti pinnu rẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na nipasẹ ẹniti a gbé ti fi i hàn!
Nwọn si bẹ̀rẹ si ibère larin ara wọn, tani ninu wọn ti yio ṣe nkan yi.
Ijà kan si mbẹ larin wọn, niti ẹniti a kà si olori ninu wọn.
O si wi fun wọn pe, Awọn ọba Keferi a ma fẹla lori wọn: a si ma pè awọn alaṣẹ wọn ni olõre.
Ṣugbọn ẹnyin kì yio ri bẹ̃: ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin ki o jẹ bi aburo; ẹniti o si ṣe olori, bi ẹniti nṣe iranṣẹ.
Nitori tali o pọ̀ju, ẹniti o joko tì onjẹ, tabi ẹniti o nṣe iranṣẹ? ẹniti o joko tì onjẹ ha kọ́? ṣugbọn emi mbẹ larin nyin bi ẹniti nṣe iranṣẹ.