Luk 20:19-26

Luk 20:19-26 YBCV

Awọn olori alufa ati awọn akọwe nwá ọna ati mu u ni wakati na; ṣugbọn nwọn bẹ̀ru awọn enia: nitoriti nwọn mọ̀ pe, o pa owe yi mọ wọn. Nwọn si nṣọ ọ, nwọn si rán awọn amí ti nwọn jẹ ẹlẹtan fi ara wọn pe olõtọ enia, ki nwọn ki o le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu, ki nwọn ki o le fi i le agbara ati aṣẹ Bãlẹ. Nwọn si bi i, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe, iwọ a ma sọrọ fun ni, iwọ a si ma kọ́-ni bi o ti tọ, bẹ̃ni iwọ kì iṣojuṣaju ẹnikan ṣugbọn iwọ nkọ́-ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ. O tọ́ fun wa lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́? Ṣugbọn o kiyesi arekereke wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò? Ẹ fi owo-idẹ kan hàn mi. Aworan ati akọle ti tani wà nibẹ? Nwọn si da a lohùn pe, Ti Kesari ni. O si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Nwọn kò si le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu niwaju awọn enia: ẹnu si yà wọn si idahùn rẹ̀, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́.

Àwọn fídíò fún Luk 20:19-26