O si ṣe, bi on ti sunmọ Jeriko, afọju kan joko lẹba ọ̀na o nṣagbe: Nigbati o gbọ́ ti ọpọ́ enia nkọja lọ, o bère pe, kili ã le mọ̀ eyi si. Nwọn si wi fun u pe, Jesu ti Nasareti li o nkọja lọ. O si kigbe pe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. Awọn ti nlọ niwaju ba a wi pe, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣugbọn on si kigbe si i kunkun pe, Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi. Jesu si dẹṣẹ duro, o ni, ki a mu u tọ̀ on wá: nigbati o si sunmọ ọ, o bi i, Wipe, Kini iwọ nfẹ ti emi iba ṣe fun o? O si wipe, Oluwa, ki emi ki o le riran. Jesu si wi fun u pe, Riran: igbagbọ́ rẹ gbà ọ là. Lojukanna o si riran, o si ntọ̀ ọ lẹhin, o nyìn Ọlọrun logo: ati gbogbo enia nigbati nwọn ri i, nwọn fi iyìn fun Ọlọrun.
Kà Luk 18
Feti si Luk 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 18:35-43
7 Days
A blind beggar crying out desperately by the side of the road, an immoral woman despised as dirty by polite society, a corrupt government employee hated by all – how could any of these people from society’s fringes hope to connect with a holy God? Based on insights from the book of Luke in the Africa Study Bible, follow Jesus as he bridges the gap between God and the marginalized.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò