Luk 18:11-13

Luk 18:11-13 YBCV

Eyi Farisi dide, o si ngbadura ninu ara rẹ̀ bayi pe, Ọlọrun, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti emi kò ri bi awọn ara iyokù, awọn alọnilọwọgba, alaiṣõtọ, panṣaga, tabi emi kò tilẹ ri bi agbowode yi. Emi ngbàwẹ li ẹrinmeji li ọ̀sẹ, mo nsan idamẹwa ohun gbogbo ti mo ni. Ṣugbọn agbowode duro li òkere, kò tilẹ jẹ gbé oju rẹ̀ soke ọrun, ṣugbọn o lù ara rẹ̀ li õkan-àiya, o wipe, Ọlọrun ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ