Luk 17:12-19

Luk 17:12-19 YBCV

Bi o si ti nwọ̀ inu iletò kan lọ, awọn ọkunrin adẹtẹ̀ mẹwa pade rẹ̀, nwọn duro li òkere: Nwọn si nahùn soke, wipe, Jesu, Olukọni ṣãnu fun wa. Nigbati o ri wọn, o wi fun wọn pe, Ẹ lọ ifi ara nyin hàn fun awọn alufa. O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, nwọn si di mimọ́. Nigbati ọkan ninu wọn ri pe a mu on larada o pada, o si fi ohùn rara yin Ọlọrun logo. O si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o ndupẹ li ọwọ rẹ̀: ara Samaria ni on si iṣe. Jesu si dahùn wipe, Awọn mẹwa ki a ṣo di mimọ́? Awọn mẹsan iyokù ha dà? A ko ri ẹnikan ti o pada wá fi ogo fun Ọlọrun, bikọse alejò yi? O si wi fun u pe, Dide, ki o si mã lọ: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada.

Àwọn fídíò fún Luk 17:12-19