O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu pe, Ọkunrin ọlọrọ̀ kan wà, ti o ni iriju kan; on na ni nwọn fi sùn u pe, o ti nfi ohun-ini rẹ̀ ṣòfo. Nigbati o si pè e, o wi fun u pe, Ẽṣe ti emi fi ngbọ́ eyi si ọ? siro iṣẹ iriju rẹ; nitori iwọ ko le ṣe iriju mọ́. Iriju na si wi ninu ara rẹ̀ pe, Ewo li emi o ṣe? nitoriti Oluwa mi gbà iṣẹ iriju lọwọ mi: emi kò le wàlẹ; lati ṣagbe oju ntì mi. Mo mọ̀ eyiti emi o ṣe, nigbati a ba mu mi kuro nibi iṣẹ iriju, ki nwọn ki o le gbà mi sinu ile wọn. O si pè awọn ajigbese oluwa rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si wi fun ekini pe, Elo ni iwọ jẹ oluwa mi? O si wipe, Ọgọrun oṣuwọn oróro. O si wi fun u pe, Mu iwe rẹ, si joko nisisiyi, ki o si kọ adọta. Nigbana li o si bi ẹnikeji pe, Elo ni iwọ jẹ? On si wipe, Ọgọrun oṣuwọn alikama. O si wi fun u pe, Mu iwe rẹ, ki o si kọ ọgọrin. Oluwa rẹ̀ si yìn alaiṣõtọ iriju na, nitoriti o fi ọgbọ́n ṣe e: awọn ọmọ aiye yi sá gbọ́n ni iran wọn jù awọn ọmọ imọlẹ lọ. Emi si wi fun nyin, ẹ fi mammoni aiṣõtọ yàn ọrẹ́ fun ara nyin pe, nigbati yio ba yẹ̀, ki nwọn ki o le gbà nyin si ibujoko wọn titi aiye.
Kà Luk 16
Feti si Luk 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 16:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò