Luk 15:20-23

Luk 15:20-23 YBCV

O si dide, o si tọ̀ baba rẹ̀ lọ. Ṣugbọn nigbati o si wà li òkere, baba rẹ̀ ri i, ãnu ṣe e, o si sure, o rọ̀mọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu. Ọmọ na si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ, emi kò yẹ li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́. Ṣugbọn baba na wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mu ãyo aṣọ wá kánkán, ki ẹ si fi wọ̀ ọ; ẹ si fi oruka bọ̀ ọ lọwọ, ati bàta si ẹsẹ rẹ̀: Ẹ si mu ẹgbọ̀rọ malu abọpa wá, ki ẹ si pa a; ki a mã jẹ, ki a si mã ṣe ariya

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ