GBOGBO awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ si sunmọ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀. Ati awọn Farisi ati awọn akọwe nkùn, wipe, ọkunrin yi ngbà ẹlẹṣẹ, o si mba wọn jẹun. O si pa owe yi fun wọn, wipe. Ọkunrin wo ni ninu nyin, ti o ni ọgọrun agutan, bi o ba sọ ọ̀kan nù ninu wọn, ti kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ ni iju, ti kì yio si tọsẹ eyi ti o nù lọ, titi yio fi ri i? Nigbati o si ri i tan, o gbé e le ejika rẹ̀, o nyọ. Nigbati o si de ile, o pè awọn ọrẹ́ ati aladugbo rẹ̀ jọ, o nwi fun wọn pe, Ẹ ba mi yọ̀; nitoriti mo ri agutan mi ti o ti nù. Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ yio wà li ọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada, jù lori olõtọ mọkandilọgọrun lọ, ti kò ṣe aini ironupiwada. Tabi obinrin wo li o ni fadaka mẹwa bi o ba sọ ọkan nù, ti kì yio tàn fitilà, ki o si gbá ile, ki o si wá a gidigidi titi yio fi ri i?
Kà Luk 15
Feti si Luk 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 15:1-8
7 days
Can you imagine feeling so seen by God that you can’t help but see others? Can you imagine your everyday, ordinary life having a significant eternal impact? This 7-day devotional from Christine Caine will help you discover how God has seen you, chosen you, and sent you to see others and to help them feel seen the way God sees them—with 20/20 vision.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò