Luk 12:42-48

Luk 12:42-48 YBCV

Oluwa si dahùn wipe, Tani olõtọ ati ọlọ́gbọn iriju na, ti oluwa rẹ̀ fi jẹ olori agbo ile rẹ̀, lati ma fi ìwọn onjẹ wọn fun wọn li akokò? Ibukun ni fun ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ti yio ba a ki o ma ṣe bẹ̃. Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio si fi i jẹ olori ohun gbogbo ti o ni. Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi yẹ̀ igba atibọ̀ rẹ̀; ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ti o si bẹ̀rẹ si ijẹ ati si imu amupara; Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti rẹ̀, ati ni wakati ti kò daba, yio si jẹ ẹ niya gidigidi, yio si yàn ipò rẹ̀ pẹlu awọn alaigbagbọ́. Ati ọmọ-ọdọ na, ti o mọ̀ ifẹ oluwa rẹ̀, ti kò si mura silẹ ti kò si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, on li a o nà pipọ. Ṣugbọn eyi ti kò mọ̀, ti o ṣe ohun ti o yẹ si lilu, on li a o lù niwọn. Nitori ẹnikẹni ti a fun ni pipọ, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère pipọ: lọdọ ẹniti a ba gbé fi pipọ si, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère si i.

Àwọn fídíò fún Luk 12:42-48