Ẹ kiyesi awọn ìwo: nwọn kì ifọnrugbin, bẹ̃ni nwọn ki kore; nwọn kò li aká, bẹ̃ni nwọn kò li abà; Ọlọrun sá mbọ́ wọn: melomelo li ẹnyin sàn jù ẹiyẹ lọ? Tani ninu nyin nipa aniyan ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀? Njẹ bi ẹnyin kò le ṣe eyi ti o kere julọ, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣaniyan nitori iyokù? Ẹ kiyesi awọn lili bi nwọn ti ndàgba: nwọn ki iṣiṣẹ nwọn ki iranwu; ṣugbọn ki emi wi fun nyin, a kò ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ́ ni gbogbo ogo rẹ̀ to ọkan ninu wọnyi. Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ tobẹ̃ eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu ina lọla; melomelo ni yio wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? Ẹ má si ṣe bere ohun ti ẹnyin ó jẹ, tabi ohun ti ẹnyin o mu, ki ẹnyin ki o má si ṣiyemeji. Nitori gbogbo nkan wọnyi ni awọn orilẹ-ède aiye nwá kiri: Baba nyin si mọ̀ pe, ẹnyin nfẹ nkan wọnyi. Ṣugbọn ẹ mã wá ijọba Ọlọrun; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún nyin. Má bẹ̀ru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin.
Kà Luk 12
Feti si Luk 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 12:24-32
7 Days
In a crowded Christmas season, most of us feel the stress and anxiety of family relationships, financial pressure, hasty decisions, and disappointed expectations. So go ahead. Take a breath. Start this Life.Church Bible Plan and realize the weight we feel may be something God never asked us to carry. How about we let go of the baggage? Let’s travel light.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò