Nigbati ijọ enia si ṣùjọ si ọdọ rẹ̀ o bẹ̀rẹ sí wipe, Iran buburu li eyi: nwọn nwá àmi; a kì yio si fi àmi kan fun u, bikoṣe àmi Jona woli. Nitori bi Jona ti jẹ àmi fun awọn ara Ninefe, gẹgẹ bẹ̃ li Ọmọ-enia yio ṣe àmi fun iran yi. Ọbabirin gusù yio dide li ọjọ idajọ pẹlu awọn enia iran yi, yio si da wọn lẹbi: nitoriti o ti iha ipẹkun aiye wá lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi. Awọn ara Ninefe yio dide li ọjọ idajọ pẹlu iran yi, nwọn o si da a lẹbi: nitoriti nwọn ronupiwada nipa iwasu Jona; si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Jona lọ mbẹ nihinyi.
Kà Luk 11
Feti si Luk 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 11:29-32
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò