Luk 1:76-80

Luk 1:76-80 YBCV

Ati iwọ, ọmọ, woli Ọgá-ogo li a o ma pè ọ: nitori iwọ ni yio ṣaju Oluwa lati tún ọ̀na rẹ̀ ṣe; Lati fi ìmọ igbala fun awọn enia rẹ̀ fun imukuro ẹ̀ṣẹ wọn, Nitori iyọ́nu Ọlọrun wa; nipa eyiti ìla-õrùn lati oke wá bojuwò wa, Lati fi imọlẹ fun awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ati lati fi ẹsẹ wa le ọ̀na alafia. Ọmọ na si dàgba, o si le li ọkàn, o si wà ni ijù titi o fi di ọjọ ifihàn rẹ̀ fun Israeli.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ