Luk 1:65-80

Luk 1:65-80 YBCV

Ẹ̀ru si ba gbogbo awọn ti mbẹ li àgbegbe wọn: a si rohin gbogbo nkan wọnyi ká gbogbo ilẹ òke Judea. Gbogbo awọn ti o gbọ́ si tò o sinu ọkàn wọn, nwọn nwipe, Irú ọmọ kili eyi yio jẹ! Ọwọ́ Oluwa si wà pẹlu rẹ̀. Sakariah baba rẹ̀ si kún fun Ẹmí Mimọ́, o si sọtẹlẹ, o ni, Olubukun li Oluwa Ọlọrun Israeli; nitoriti o ti bojuwò, ti o si ti dá awọn enia rẹ̀ nide, O si ti gbé iwo igbala soke fun wa ni ile Dafidi ọmọ-ọdọ rẹ̀; Bi o ti wi li ẹnu awọn woli rẹ̀ mimọ́, ti nwọn ti mbẹ nigbati aiye ti ṣẹ̀: Pe, a o gbà wa là lọwọ awọn ọtá wa, ati lọwọ gbogbo awọn ti o korira wa; Lati ṣe ãnu ti o ti leri fun awọn baba wa, ati lati ranti majẹmu rẹ̀ mimọ́, Ara ti o ti bú fun Abrahamu baba wa, Pe on o fifun wa, lati gbà wa lọwọ awọn ọtá wa, ki awa ki o le ma sìn i laifòya, Ni mimọ́ ìwa ati li ododo niwaju rẹ̀, li ọjọ aiye wa gbogbo. Ati iwọ, ọmọ, woli Ọgá-ogo li a o ma pè ọ: nitori iwọ ni yio ṣaju Oluwa lati tún ọ̀na rẹ̀ ṣe; Lati fi ìmọ igbala fun awọn enia rẹ̀ fun imukuro ẹ̀ṣẹ wọn, Nitori iyọ́nu Ọlọrun wa; nipa eyiti ìla-õrùn lati oke wá bojuwò wa, Lati fi imọlẹ fun awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ati lati fi ẹsẹ wa le ọ̀na alafia. Ọmọ na si dàgba, o si le li ọkàn, o si wà ni ijù titi o fi di ọjọ ifihàn rẹ̀ fun Israeli.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ