Aaroni si sunmọ pẹpẹ, o si pa ọmọ malu ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikalarẹ̀. Awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá: o si tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, o si tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ: Ṣugbọn ọrá, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, o sun u lori pẹpẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. Ati ẹran ati awọ li o fi iná sun lẹhin ibudó. O si pa ẹbọ sisun: awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká. Nwọn si mú ẹbọ sisun tọ̀ ọ wá, ti on ti ipín rẹ̀, ati ori: o si sun wọn lori pẹpẹ. O si ṣìn ifun ati itan rẹ̀, o si sun wọn li ẹbọ sisun lori pẹpẹ.
Kà Lef 9
Feti si Lef 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Lef 9:8-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò