O si mú ọrẹ-ẹbọ awọn enia wá, o si mú obukọ, ti iṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, o si pa a, o si fi i rubọ ẹ̀ṣẹ, bi ti iṣaju. O si mú ẹbọ sisun wá, o si ru u gẹgẹ bi ìlana na. O si mú ẹbọ ohunjijẹ wá, o si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, o si sun u lori pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀. O si pa akọmalu ati àgbo fun ẹbọ alafia, ti iṣe ti awọn enia; awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká. Ati ọrá inu akọmalu na ati ti inu àgbo na, ìru rẹ̀ ti o lọrá, ati eyiti o bò ifun, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ: Nwọn si fi ọrá na lé ori igẹ̀ wọnni, o si sun ọrà na lori pẹpẹ. Ati igẹ̀ na ati itan ọtún ni Aaroni fì li ẹbọ fifì niwaju OLUWA; bi Mose ti fi aṣẹ lelẹ. Aaroni si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke si awọn enia, o si sure fun wọn; o si sọkalẹ kuro ni ibi irubọ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹbọ sisun, ati ẹbọ alafia. Mose ati Aaroni si wọ̀ inu agọ́ ajọ, nwọn si jade, nwọn si sure fun awọn enia: ogo OLUWA si farahàn fun gbogbo enia. Iná kan si ti ọdọ OLUWA jade wá, o si jó ẹbọ sisun ati ọrá ori pẹpẹ na; nigbati gbogbo awọn enia ri i, nwọn hó kùhu, nwọn si dojubolẹ.
Kà Lef 9
Feti si Lef 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Lef 9:15-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò