Lef 7:22-27

Lef 7:22-27 YBCV

OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ọrákọra akọmalu, tabi ti agutan, tabi ti ewurẹ. Ati ọrá ẹran ti o tikara rẹ̀ kú, ati ọrá eyiti ẹranko fàya, on ni ki a ma lò ni ilò miran: ṣugbọn ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ. Nitoripe ẹnikẹni ti o ba jẹ ọrá ẹran, ninu eyiti enia mú rubọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ani ọkàn ti o ba jẹ ẹ on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. Pẹlupẹlu ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ, iba ṣe ti ẹiyẹ tabi ti ẹran, ninu ibugbé nyin gbogbo. Ọkànkọkàn ti o ba jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.