EYI si li ofin ẹbọ ẹbi: mimọ́ julọ ni. Ni ibi ti nwọn gbé pa ẹbọ sisun ni ki nwọn ki o pa ẹbọ ẹbi: ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ yiká. Ki o si fi gbogbo ọrá inu rẹ̀ rubọ; ìru rẹ̀ ti o lọrá, ati ọrá ti o bò ifun lori, Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe, on ni ki o mú kuro: Ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ẹbọ ẹbi ni. Gbogbo ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: ni ibi mimọ́ kan ki a jẹ ẹ: mimọ́ julọ ni. Bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ si li ẹbọ ẹbi: ofin kan ni fun wọn: alufa ti nfi i ṣètutu ni ki on ní i. Ati alufa ti nru ẹbọ sisun ẹnikẹni, ani alufa na ni yio ní awọ ẹran ẹbọ sisun, ti o ru fun ara rẹ̀. Ati gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti a yan ninu àro, ati gbogbo eyiti a yan ninu apẹ, ati ninu awopẹtẹ, ni ki o jẹ́ ti alufa ti o ru u. Ati gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti a fi oróro pò, ati gbigbẹ, ni ki gbogbo awọn ọmọ Aaroni ki o ní, ẹnikan bi ẹnikeji rẹ̀.
Kà Lef 7
Feti si Lef 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Lef 7:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò