OLUWA si sọ fun Mose pe,
Paṣẹ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ sisun: Ẹbọ sisun ni, nitori sisun rẹ̀ lori pẹpẹ ni gbogbo oru titi di owurọ̀, iná pẹpẹ na yio si ma jò ninu rẹ̀.
Ki alufa ki o si mú ẹ̀wu ọ̀gbọ rẹ̀ wọ̀, ati ṣòkoto ọ̀gbọ rẹ̀ nì ki o fi si ara rẹ̀, ki o si kó ẽru ti iná jọ, ti on ti ẹbọ sisun lori pẹpẹ, ki o si fi i si ìha pẹpẹ.
Ki o si bọ́ ẹ̀wu rẹ̀ silẹ, ki o si mú ẹ̀wu miran wọ̀, ki o si gbé ẽru wọnni jade lọ sẹhin ibudó si ibi kan ti o mọ́.
Ki iná ori pẹpẹ nì ki o si ma jó lori rẹ̀; ki a máṣe pa a; ki alufa ki o si ma kòná igi lori rẹ̀ li orowurọ̀, ki o si tò ẹbọ sisun sori rẹ̀; ki o si ma sun ọrá ẹbọ alafia lori rẹ̀.
Ki iná ki o ma jó titi lori pẹpẹ na; kò gbọdọ kú lai.
Eyi si li ofin ẹbọ ohunjijẹ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o ru u niwaju OLUWA, niwaju pẹpẹ.
Ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun didara ẹbọ ohunjijẹ na, ati ti oróro rẹ̀, ati gbogbo turari ti mbẹ lori ẹbọ ohunjijẹ, ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn, ani fun iranti rẹ̀, si OLUWA.
Iyokù rẹ̀ ni Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio jẹ: àkara alaiwu ni, ki a jẹ ẹ ni ibi mimọ́; ni agbalá agọ́ ajọ ni ki nwọn ki o jẹ ẹ.
Ki a máṣe fi iwukàra yan a. Mo ti fi i fun wọn ni ipín ti wọn ninu ẹbọ mi ti a fi iná ṣe; mimọ́ julọ ni, bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ ẹbi.
Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn ọmọ Aaroni ni ki o jẹ ninu rẹ̀, yio jasi aṣẹ titilai ni iraniran nyin, nipa ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: ẹnikẹni ti o ba kàn wọn yio di mimọ́.
OLUWA si sọ fun Mose pe,
Eyi li ọrẹ-ẹbọ Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn o ru si OLUWA, li ọjọ́ ti a fi oróro yàn a; idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ titilai, àbọ rẹ̀ li owurọ̀, ati àbọ rẹ̀ li alẹ.
Ninu awopẹtẹ ni ki a fi oróro ṣe e; nigbati a ba si bọ̀ ọ, ki iwọ ki o si mú u wọ̀ ile: ati ìṣu yiyan ẹbọ ohunjijẹ na ni ki iwọ ki o fi rubọ õrùn didùn si OLUWA.
Ati alufa ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti a fi oróro yàn ni ipò rẹ̀ ni ki o ru u: aṣẹ titilai ni fun OLUWA, sisun ni ki a sun u patapata.
Nitori gbogbo ẹbọ ohunjijẹ alufa, sisun ni ki a sun u patapata: a kò gbọdọ jẹ ẹ.