Lef 27:30-34

Lef 27:30-34 YBCV

Ati gbogbo idamẹwa ilẹ na ibaṣe ti irugbìn ilẹ na, tabi ti eso igi, ti OLUWA ni: mimọ́ ni fun OLUWA. Bi o ba ṣepe enia ba ràpada rára ninu ohun idamẹwa rẹ̀, ki o si fi idamarun kún u. Ati gbogbo idamẹwa ọwọ́ ẹran, tabi ti agbo-ẹran, ani ohunkohun ti o ba kọja labẹ ọpá, ki ẹkẹwa ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA. Ki o máṣe yẹ̀ ẹ wò bi o jẹ́ rere tabi buburu, bẹ̃li on kò gbọdọ pàrọ rẹ̀: bi o ba si ṣepe o pàrọ rẹ̀ rára, njẹ ati on ati ipàrọ rẹ̀ yio jẹ́ mimọ́; a kò gbọdọ rà a pada. Wọnyi li ofin, ti OLUWA palaṣẹ fun Mose fun awọn ọmọ Israeli li òke Sinai.