Lef 27:30-32

Lef 27:30-32 YBCV

Ati gbogbo idamẹwa ilẹ na ibaṣe ti irugbìn ilẹ na, tabi ti eso igi, ti OLUWA ni: mimọ́ ni fun OLUWA. Bi o ba ṣepe enia ba ràpada rára ninu ohun idamẹwa rẹ̀, ki o si fi idamarun kún u. Ati gbogbo idamẹwa ọwọ́ ẹran, tabi ti agbo-ẹran, ani ohunkohun ti o ba kọja labẹ ọpá, ki ẹkẹwa ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA.