Lef 26:44-45

Lef 26:44-45 YBCV

Ṣugbọn sibẹ̀ ninu gbogbo eyina, nigbati nwọn ba wà ni ilẹ awọn ọtá wọn, emi ki yio tà wọn nù, bẹ̃li emi ki yio korira wọn, lati run wọn patapata, ati lati dà majẹmu mi pẹlu wọn: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun wọn: Ṣugbọn nitori wọn emi o ranti majẹmu awọn baba nla wọn, ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá li oju awọn orilẹ-ède, ki emi ki o le ma ṣe Ọlọrun wọn: Emi li OLUWA.