Lef 26:34-39

Lef 26:34-39 YBCV

Nigbana ni ilẹ na yio ní isimi rẹ̀, ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀, ẹnyin o si wà ni ilẹ awọn ọtá nyin; nigbana ni ilẹ yio simi, ti yio si ní isimi rẹ̀. Ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀ ni yio ma simi; nitoripe on kò simi li ọjọ́-isimi nyin, nigbati ẹnyin ngbé inu rẹ̀. Ati lara awọn ti o kù lãye ninu nyin, li emi o rán ijàiya si ọkàn wọn ni ilẹ awọn ọtá wọn: iró mimì ewé yio si ma lé wọn; nwọn o si sá, bi ẹni sá fun idà; nwọn o si ma ṣubu nigbati ẹnikan kò lepa. Nwọn o si ma ṣubulù ara wọn, bi ẹnipe niwaju idà, nigbati kò sí ẹniti nlepa: ẹnyin ki yio si lí agbara lati duro niwaju awọn ọtá nyin. Ẹnyin o si ṣegbé ninu awọn orilẹ-ède, ilẹ awọn ọtá nyin yio si mú nyin jẹ. Ati awọn ti o kù ninu nyin yio si joro ninu ẹ̀ṣẹ wọn ni ilẹ awọn ọtá nyin; ati nitori ẹ̀ṣẹ awọn baba wọn pẹlu ni nwọn o ma joro pẹlu wọn.