Bi ẹnyin kò ba gbà ìkilọ mi nipa nkan wọnyi, ṣugbọn ti ẹnyin o ma rìn lodi si mi; Nigbana li emi pẹlu yio ma rìn lodi si nyin, emi o si jẹ nyin ni ìya si i ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin. Emi o si mú idà wá sori nyin, ti yio gbà ẹsan majẹmu mi; a o si kó nyin jọ pọ̀ ninu ilu nyin, emi o rán ajakalẹ-àrun sãrin nyin; a o si fi nyin lé ọtá lọwọ. Nigbati mo ba ṣẹ́ ọpá onjẹ nyin, obinrin mẹwa yio yan àkara nyin ninu àro kan, ìwọ̀n ni nwọn o si ma fi fun nyin li àkara nyin: ẹnyin o si ma jẹ, ẹ ki yio si yó. Ninu gbogbo eyi bi ẹnyin kò ba si gbọ́ ti emi, ti ẹ ba si nrìn lodi si mi; Nigbana li emi o ma rìn lodi si nyin pẹlu ni ikannu; emi pẹlu yio si nà nyin ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin. Ẹnyin o si jẹ ẹran-ara awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati ẹran-ara awọn ọmọ nyin obinrin li ẹnyin o jẹ. Emi o si run ibi giga nyin wọnni, emi o si ke ere nyin lulẹ, emi o si wọ́ okú nyin sori okú oriṣa nyin; ọkàn mi yio si korira nyin. Emi o si sọ ilu nyin di ahoro, emi o si sọ ibi mimọ́ nyin di ahoro, emi ki yio gbọ́ adùn õrùn didùn nyin mọ́. Emi o si sọ ilẹ na di ahoro: ẹnu yio si yà awọn ọtá nyin ti ngbé inu rẹ̀ si i. Emi o si tú nyin ká sinu awọn orilẹ-ède, emi o si yọ idà tì nyin lẹhin: ilẹ nyin yio si di ahoro, ati ilu nyin yio di ahoro.
Kà Lef 26
Feti si Lef 26
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Lef 26:23-33
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò