Lef 19:35-37

Lef 19:35-37 YBCV

Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ, ni ìwọn ọpá, ni òṣuwọn iwuwo, tabi ni òṣuwọn oninu. Oṣuwọn otitọ, òṣuwọn iwuwo otitọ, òṣuwọn efa otitọ, ati òṣuwọn hini otitọ, ni ki ẹnyin ki o ní: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá. Nitorina ni ki ẹnyin ki o si ma kiyesi gbogbo ìlana mi, ati si gbogbo idajọ mi, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA.