Lef 19:11-13

Lef 19:11-13 YBCV

Ẹnyin kò gbọdọ jale, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe alaiṣõtọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣeké fun ara nyin. Ẹnyin kò si gbọdọ fi orukọ mi bura eké, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA. Iwọ kò gbọdọ rẹ́ ẹnikeji rẹ jẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ haramu: owo ọ̀ya alagbaṣe kò gbọdọ sùn ọdọ rẹ titi di owurọ̀.