OLUWA si sọ fun Mose pe,
Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
Ẹnyin kò gbọdọ hùwa bi ìwa ilẹ Egipti nibiti ẹnyin ti ngbé: ẹnyin kò si gbọdọ hùwa ìwa ilẹ Kenaani, nibiti emi o mú nyin lọ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ rìn nipa ìlana wọn.
Ki ẹnyin ki o ma ṣe ofin mi, ki ẹnyin si ma pa ìlana mi mọ́, lati ma rìn ninu wọn: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
Ẹnyin o si ma pa ìlana mi mọ́, ati ofin mi: eyiti bi enia ba ṣe, on o ma yè ninu wọn: Emi li OLUWA.
Ẹnikẹni kò gbọdọ sunmọ ẹnikan ti iṣe ibatan rẹ̀ lati tú ìhoho rẹ̀: Emi li OLUWA.
Ihoho baba rẹ, tabi ìhoho iya rẹ̀, ni iwọ kò gbọdọ tú: iya rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.
Ihoho aya baba rẹ ni iwọ kò gbọdọ tú: ìhoho baba rẹ ni.
Ihoho arabinrin rẹ, ọmọ baba rẹ, tabi ọmọ iya rẹ, ti a bi ni ile, tabi ti a bi li ode, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú.
Ìhoho ọmọbinrin ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ti ọmọbinrin ọmọ rẹ obinrin, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú: nitoripe ìhoho ara rẹ ni nwọn.
Ìhoho ọmọbinrin aya baba rẹ, ti a bi lati inu baba rẹ wá, arabinrin rẹ ni, iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin baba rẹ: ibatan baba rẹ ni.
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ: nitoripe ibatan iya rẹ ni.
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arakunrin baba rẹ, iwọ kò gbọdọ sunmọ aya rẹ̀: arabinrin baba rẹ ni.
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya ọmọ rẹ: nitoripe aya ọmọ rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya arakunrin rẹ: ìhoho arakunrin rẹ ni.
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho obinrin ati ti ọmọbinrin rẹ̀; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ obinrin, lati tú ìhoho wọn; nitoripe ibatan ni nwọn: ohun buburu ni.
Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ́ arabinrin aya rẹ li aya, lati bà a ninu jẹ́, lati tú ìhoho rẹ̀, pẹlu rẹ̀ nigbati o wà lãye.
Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ sunmọ obinrin kan lati tú u ni ìhoho, ni ìwọn igbati a yà a sapakan nitori aimọ́ rẹ̀.
Pẹlupẹlu iwọ kò gbọdọ bá aya ẹnikeji rẹ dàpọ lati bà ara rẹ jẹ́ pẹlu rẹ̀.
Iwọ kò si gbọdọ fi irú-ọmọ rẹ kan fun Moleki, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA.