Lef 15:25-27

Lef 15:25-27 YBCV

Ati bi obinrin kan ba ní isun ẹ̀jẹ li ọjọ́ pupọ̀ le ìgba ìyasapakan rẹ̀; tabi bi o ba si sun rekọja ìgba ìyasapakan rẹ̀; gbogbo ọjọ́ isun aimọ́ rẹ̀ yio si ri bi ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀: o jẹ́ alaimọ́. Gbogbo akete ti o dubulẹ lé ni gbogbo ọjọ́ isun rẹ̀ ki o si jẹ́ fun u bi akete ìyasapakan rẹ̀: ati ohunkohun ti o joko lé ki o jẹ́ aimọ́, bi aimọ́ ìyasapakan rẹ̀. Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn nkan wọnni ki o jẹ́ alaimọ́, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ̀ alaimọ́ titi di aṣalẹ.