Ati bi ohun irú ìdapọ ọkunrin ba ti ara rẹ̀ jade, nigbana ni ki o wẹ̀ gbogbo ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ati gbogbo aṣọ, ati gbogbo awọ, lara eyiti ohun irú ìdapọ ba wà, on ni ki a fi omi fọ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ati obinrin na, ẹniti ọkunrin ba bá dàpọ ti on ti ohun irú ìdapọ, ki awọn mejeji ki o wẹ̀ ninu omi, ki nwọn ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Bi obinrin kan ba si ní isun, ti isun rẹ̀ li ara rẹ̀ ba jasi ẹ̀jẹ, ki a yà a sapakan ni ijọ́ meje: ẹnikẹni ti o ba si farakàn a, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ati ohun gbogbo ti o dubulẹ lé ninu ile ìyasapakan rẹ̀ yio jẹ́ aimọ́: ohunkohun pẹlu ti o joko lé yio jẹ́ aimọ́. Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Bi o ba si ṣepe lara akete rẹ̀ ni, tabi lara ohun ti o joko lé, nigbati o ba farakàn a, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Bi ọkunrin kan ba si bá a dàpọ rára, ti ohun obinrin rẹ̀ ba mbẹ lara ọkunrin na, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; ati gbogbo akete ti on dubulẹ lé ki o jẹ́ aimọ́.
Kà Lef 15
Feti si Lef 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Lef 15:16-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò