Lef 15:1-3

Lef 15:1-3 YBCV

OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnikan ba ní àrun isun lara rẹ̀, nitori isun rẹ̀ alaimọ́ li on. Eyi ni yio si jẹ́ aimọ́ rẹ̀ ninu isun rẹ̀: ara rẹ̀ iba ma sun isun rẹ̀, tabi bi ara rẹ̀ si dá kuro ninu isun rẹ̀, aimọ́ rẹ̀ ni iṣe.