OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnikan ba ní àrun isun lara rẹ̀, nitori isun rẹ̀ alaimọ́ li on.
Eyi ni yio si jẹ́ aimọ́ rẹ̀ ninu isun rẹ̀: ara rẹ̀ iba ma sun isun rẹ̀, tabi bi ara rẹ̀ si dá kuro ninu isun rẹ̀, aimọ́ rẹ̀ ni iṣe.
Gbogbo ori akete ti ẹniti o ní isun na ba dubulẹ lé, aimọ́ ni: ati gbogbo ohun ti o joko lé yio jẹ́ alaimọ́.
Ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀ ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
Ẹniti o si joko lé ohunkohun ti ẹniti o ní isun ti joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
Ẹniti o si farakàn ara ẹniti o ní isun, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
Bi ẹniti o ní isun ba tutọ sara ẹniti o mọ́; nigbana ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
Ati asákasá ti o wù ki ẹniti o ní isun ki o gùn ki o jẹ́ alaimọ́.
Ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o wà nisalẹ rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ati ẹniti o rù ohun kan ninu nkan wọnni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
Ati ẹnikẹni ti ẹniti o ní isun ba farakàn, ti kò ti wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ ninu omi, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
Ati ohunèlo amọ̀, ti ẹniti o ní isun ba fọwọkàn, fifọ́ ni ki a fọ́ ọ: ati gbogbo ohunèlo igi ni ki a ṣàn ninu omi.
Nigbati ẹniti o ní isun ba si di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, fun isọdimimọ́ rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi ti nṣàn, yio si jẹ́ mimọ́.
Ati ni ijọ́ kẹjọ, ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji fun ara rẹ̀, ki o si wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki o si fi wọn fun alufa:
Ki alufa ki o si fi wọn rubọ, ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun; ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori isun rẹ̀.