Lef 13:9-17

Lef 13:9-17 YBCV

Nigbati àrun ẹ̀tẹ ba mbẹ li ara enia, nigbana ni ki a mú u tọ̀ alufa wá; Ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi iwú na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ti o si sọ irun rẹ̀ di funfun, ti õju si mbẹ ninu iwú na, Ẹ̀tẹ lailai ni li awọ ara rẹ̀, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ki o máṣe sé e mọ́; nitoripe alaimọ́ ni. Bi ẹ̀tẹ ba si sọ jade kakiri li awọ ara, ti ẹ̀tẹ na ba si bò gbogbo ara ẹniti o ní àrun na, lati ori rẹ̀ titi dé ẹsẹ̀ rẹ̀, nibikibi ti alufa ba wò; Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi ẹ̀tẹ na ba bò gbogbo ara rẹ̀, ki o pè àlarun na ni mimọ́; gbogbo rẹ̀ di funfun: mimọ́ li on. Ṣugbọn ni ijọ́ ti õju na ba hàn ninu rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́. Ki alufa ki o wò õju na, ki o si pè e li alaimọ́: nitoripe aimọ́ li õju: ẹ̀tẹ ni. Tabi bi õju na ba yipada, ti o si di funfun, ki o si tọ̀ alufa wá, Alufa yio si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba di funfun, nigbana ni ki alufa ki o pè àlarun na ni mimọ́: mimọ́ li on.