Ati bi ẹran kan, ninu eyiti ẹnyin ba ma jẹ, ba kú; ẹniti o ba farakàn okú rẹ̀ yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ẹniti o ba si jẹ ninu okú rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ẹniti o ba si rù okú rẹ̀ ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ yio jasi irira; a ki yio jẹ ẹ. Ohunkohun ti nfi inu wọ́, ati ohunkohun ti nfi mẹrẹrin rìn, ati ohunkohun ti o ba ní ẹsẹ̀ pupọ̀, ani ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, awọn li ẹnyin kò gbọdọ jẹ; nitoripe irira ni nwọn. Ẹnyin kò gbọdọ fi ohun kan ti nrakò, sọ ara nyin di irira, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi wọn sọ ara nyin di alaimọ́ ti ẹnyin o fi ti ipa wọn di elẽri. Nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin: nitorina ni ki ẹnyin ki o yà ara nyin si mimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́; nitoripe mimọ́ li Emi: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi ohunkohun ti nrakò sọ ara nyin di elẽri. Nitoripe Emi li OLUWA ti o mú nyin gòke ti ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: nitorina ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́, nitoripe mimọ́ li Emi. Eyiyi li ofin ẹranko, ati ti ẹiyẹ, ati ti ẹda gbogbo alãye ti nrá ninu omi, ati ti ẹda gbogbo ti nrakò lori ilẹ: Lati fi iyatọ sãrin aimọ́ ati mimọ́, ati sãrin ohun alãye ti a ba ma jẹ, ati ohun alãye ti a ki ba jẹ.
Kà Lef 11
Feti si Lef 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Lef 11:39-47
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò