Ẹk. Jer 3:55-60

Ẹk. Jer 3:55-60 YBCV

Emi kepe orukọ rẹ, Oluwa, lati iho jijin wá. Iwọ ti gbọ́ ohùn mi: máṣe se eti rẹ mọ si imikanlẹ mi, si igbe mi. Iwọ sunmọ itosi li ọjọ ti emi kigbe pè ọ: iwọ wipe: Má bẹ̀ru! Oluwa, iwọ ti gba ijà mi jà; iwọ ti rà ẹmi mi pada. Oluwa, iwọ ti ri inilara mi, ṣe idajọ ọran mi! Iwọ ti ri gbogbo igbẹsan wọn, gbogbo èro buburu wọn si mi.