Jud 1:8-11

Jud 1:8-11 YBCV

Bakanna ni awọn wọnyi pẹlu nsọ ara di ẽri ninu àlá wọn, nwọn si ngan ijoye, nwọn si nsọ̀rọ buburu si awọn ọlọlá. Ṣugbọn Mikaeli, olori awọn angẹli, nigbati o mba Èṣu jà, ti o nṣì jijakadi nitori okú Mose, kò si gbọdọ sọ ọ̀rọ-odi si i, ṣugbọn o wipe, Oluwa ni yio ba ọ wi. Ṣugbọn awọn wọnyi nsọ̀rọ-òdi si ohun gbogbo ti nwọn kò mọ̀: ṣugbọn ohun gbogbo ti nwọn mọ̀ nipa ẹda, bi ẹranko tí kò ni iyè, ninu nkan wọnyi ni nwọn di ẹni iparun. Egbé ni fun wọn! Nitoriti nwọn ti rìn li ọ̀na Kaini, nwọn si fi iwọra súré sinu ìṣina Balaamu nitori ère, nwọn si ṣegbé ninu iṣọtẹ̀ Kora.