Jud 1:3-4

Jud 1:3-4 YBCV

Olufẹ, nigbati mo fi aisimi gbogbo kọwe si nyin niti igbala ti iṣe ti gbogbo enia, nko gbọdọ ṣaima kọwé si nyin, ki n si gbà nyin niyanju lati mã ja gidigidi fun igbagbọ́, ti a ti fi lé awọn enia mimọ́ lọwọ lẹ̃kanṣoṣo. Nitori awọn enia kan mbẹ ti nwọn nyọ́ wọle, awọn ẹniti a ti yàn lati igbà atijọ si ẹbi yi, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti nyi ore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti nwọn si nsẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo na, ani Jesu Kristi Oluwa.