Ṣugbọn ẹnyin olufẹ, ẹ ranti awọn ọ̀rọ ti a ti sọ ṣaju lati ọwọ́ awọn Aposteli Oluwa wa Jesu Kristi; Bi nwọn ti wi fun nyin pe, awọn ẹlẹgàn yio wà nigba ikẹhin, ti nwọn o mã rìn gẹgẹ bi ifẹkufẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti ara wọn. Awọn wọnyi ni awọn ẹniti nya ara wọn si ọtọ, awọn ẹni ti ara, ti nwọn kò ni Ẹmí. Ṣugbọn ẹnyin, olufẹ, ti ẹ ngbe ara nyin ró lori ìgbagbọ́ nyin ti o mọ́ julọ, ti ẹ ngbadura ninu Ẹmí Mimọ́, Ẹ mã pa ara nyin mọ́ ninu ifẹ Ọlọrun, ẹ mã reti ãnu Oluwa wa Jesu Kristi titi di iye ainipẹkun.
Kà Jud 1
Feti si Jud 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jud 1:17-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò