Kiyesi i, apoti majẹmu OLUWA gbogbo aiye ngòke lọ ṣaju nyin lọ si Jordani. Njẹ nitorina, ẹ mu ọkunrin mejila ninu awọn ẹ̀ya Israeli, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya. Yio si ṣe, lojukanna bi atẹlẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti OLUWA, Oluwa gbogbo aiye, ba ti tẹ̀ omi Jordani, omi Jordani yio ke kuro, ani omi ti nti òke ṣànwá; yio si duro bi òkiti kan. O si ṣe, nigbati awọn enia ṣí kuro ninu agọ́ wọn, lati gòke Jordani, ti awọn alufa si rù apoti majẹmu wà niwaju awọn enia; Bi awọn ti o rù apoti si ti dé Jordani, ti awọn alufa ti o rù apoti na si tẹ̀ ẹsẹ̀ wọn bọ̀ eti omi na, (nitoripe odò Jordani a ma kún bò gbogbo bèbe rẹ̀ ni gbogbo akokò ikore,) Ni omi ti nti oke ṣàn wá duro, o si ga jìna rére bi òkiti li ọnà ni ilu Adamu, ti o wà lẹba Saretani: eyiti o si ṣàn sodò si ìha okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, a ke wọn kuro patapata: awọn enia si gòke tàra si Jeriko. Awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA, si duro ṣinṣin lori ilẹ gbigbẹ lãrin Jordani, ati gbogbo awọn enia Israeli kọja lori ilẹ gbigbẹ, titi gbogbo awọn enia na fi gòke Jordani tán.
Kà Joṣ 3
Feti si Joṣ 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joṣ 3:11-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò