Joṣ 14:6-9

Joṣ 14:6-9 YBCV

Nigbana ni awọn ọmọ Juda wá sọdọ Joṣua ni Gilgali: Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ ohun ti OLUWA wi fun Mose enia Ọlọrun nipa temi tirẹ ni Kadeṣi-barnea. Ẹni ogoji ọdún ni mi nigbati Mose iranṣẹ OLUWA rán mi lati Kadeṣi-barnea lọ ṣamí ilẹ na; mo si mú ìhin fun u wá gẹgẹ bi o ti wà li ọkàn mi. Ṣugbọn awọn arakunrin mi ti o gòke lọ já awọn enia li àiya: ṣugbọn emi tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata. Mose si bura li ọjọ́ na wipe, Nitõtọ ilẹ ti ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ nì, ilẹ-iní rẹ ni yio jẹ́, ati ti awọn ọmọ rẹ lailai, nitoriti iwọ tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata.