Jona si jade kuro ni ilu na, o si joko niha ila-õrun ilu na, o si pa agọ kan nibẹ fun ara rẹ̀, o si joko ni iboji labẹ rẹ̀, titi yio fi ri ohun ti yio ṣe ilu na. Oluwa Ọlọrun si pese itakùn kan, o si ṣe e ki o goke wá sori Jona; ki o le ṣiji bò o lori; lati gbà a kuro ninu ibinujẹ rẹ̀. Jona si yọ ayọ̀ nla nitori itakùn na. Ṣugbọn Ọlọrun pese kokorò kan nigbati ilẹ mọ́ ni ijọ keji, o si jẹ itakùn na, o si rọ. O si ṣe, nigbati õrun là, Ọlọrun si pese ẹfufu gbigbona ti ila-õrùn; õrùn si pa Jona lori, tobẹ̃ ti o rẹ̀ ẹ, o si fẹ́ ninu ara rẹ̀ lati kú, o si wipe, O sàn fun mi lati kú jù ati wà lãyè lọ.
Kà Jon 4
Feti si Jon 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jon 4:5-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò