ṢUGBỌN o bà Jona ninu jẹ́ gidigidi, o si binu pupọ̀. O si gbadura si Oluwa, o si wipe, Emi bẹ ọ, Oluwa, ọ̀rọ mi kọ yi nigbati mo wà ni ilẹ mi? nitorina ni mo ṣe salọ si Tarṣiṣi ni iṣaju: nitori emi mọ̀ pe, Ọlọrun olore-ọfẹ ni iwọ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ, o si ronupiwada ibi na. Njẹ nitorina, Oluwa, emi bẹ ọ, gbà ẹmi mi kuro lọwọ mi nitori o sàn fun mi lati kú jù ati wà lãyè. Nigbana ni Oluwa wipe, Iwọ ha ṣe rere lati binu? Jona si jade kuro ni ilu na, o si joko niha ila-õrun ilu na, o si pa agọ kan nibẹ fun ara rẹ̀, o si joko ni iboji labẹ rẹ̀, titi yio fi ri ohun ti yio ṣe ilu na.
Kà Jon 4
Feti si Jon 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jon 4:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò