Jon 2:3-7

Jon 2:3-7 YBCV

Nitoriti iwọ ti sọ mi sinu ibu, larin okun; iṣàn omi si yi mi kakiri; gbogbo bibì omi ati riru omi rẹ kọja lori mi. Nigbana ni mo wipe, A ta mi nù kuro niwaju rẹ; ṣugbọn sibẹ emi o tun ma wo iha tempili mimọ́ rẹ. Omi yi mi kakiri, ani titi de ọkàn; ibu yi mi kakiri, a fi koriko-odò wé mi lori. Emi sọkalẹ lọ si isalẹ awọn oke nla; ilẹ aiye pẹlu idenà rẹ̀ wà yi mi ka titi: ṣugbọn iwọ ti mu ẹmi mi wá soke lati inu ibú wá, Oluwa Ọlọrun mi. Nigbati o rẹ ọkàn mi ninu mi, emi ranti Oluwa: adura mi si wá sọdọ rẹ sinu tempili mimọ́ rẹ.