Joel 1:2-7

Joel 1:2-7 YBCV

Gbọ́ eyi, ẹnyin arugbo, si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ na. Eyi ha wà li ọjọ nyin, tabi li ọjọ awọn baba nyin? Ẹ sọ ọ fun awọn ọmọ nyin, ati awọn ọmọ nyin fun awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ wọn fun iran miràn. Eyi ti iru kòkoro kan jẹ kù ni ẽṣú jẹ; ati eyi ti ẽṣú jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ; eyiti kòkoro na si jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ. Ji, ẹnyin ọmùti, ẹ si sọkun; si hu, gbogbo ẹnyin ọmùti waini, nitori ọti-waini titun; nitoriti a ké e kuro li ẹnu nyin. Nitori orilẹ-ède kan goke wá si ilẹ mi, o li agbara, kò si ni iye, ehin ẹniti iṣe ehin kiniun, o si ni erìgi abo kiniun. O ti pa àjara mi run, o si ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọtọ́ mi kuro, o ti bó o jalẹ, o si sọ ọ nù; awọn ẹ̀ka rẹ̀ li a si sọ di funfun.